Nigeria Language Syllabus, Yoruba Language scheme of work primary 1 Federal, álífábëêtì Yorùbá, Orin eré ìdárayá, Igba Ninu Odun.
FIRST TERM SCHEME OF WORK FOR YORUBA LANGUAGE PRIMARY 1
YORÙBÁ PRIMARY 1 TÁÀMÙ KÌN-ÍN-NÍ
ÕSÊ 1
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
ÀŚÀ: Ìkíni ní ilê Yorùbá
ÀKÓÓNÚ IŚË
- ìkíni àti ìdáhùn fún ôjö
- ìkíni ní onírúurú iśë. Bí àpççrç iśë àgbê, iśë awakõ abbl
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
- Darí akëkõö láti fi bí a śe ń kí ni śeré.
- Fi àwòrán àwôn tó ń kí ara wôn han akëkõö.
AKËKÕÖ
- Sô ohun tí wôn mõ nípa àśà ìkíni sáájú ìdánilëkõö.
- Śe àpççrç àwôn oríśi ìkíni tí wôn ti gbö rí OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
Àwòrán ènìyàn tó ń kí ara wôn
ÕSÊ 2
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
ÁLÍFÁBËÊTÌ ÈDÈ YORÙBÁ
ÀKÓÓNÚ IŚË
Kíkô álífábëêtì Yorùbá sára pátákó ìkõwé
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
- Kô álífábëêtì Yorùbá sí ara pátákó
- Ka àwôn álífábëêtì Yorùbá náà sí etígbõö àwôn akëkõö
- Ka àwôn álífábëêtì Yorùbá náà kí akëkõö máa pè é têlé e
- Pe akëkõö láti kà á.
AKËKÕÖ
- Fi etí sílê bí olùkö śe ń ka álífábëêtì Yorùbá náà.
- Śe ìdámõ àwôn álífábëêtì Yorùbá náà lára pátákó
- pè é têlé olùkö bí ó śe ń kà á.
OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
- Pátákó ìkõwé
- Káàdì aláfihàn
- Pátákó çlëmõön
ÕSÊ 3
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
SÍŚÊDÁ ÕRÕ PÊLÚ ÁLÍFÁBËÊTÌ (A – K)
ÀKÓÓNÚ IŚË
Kíkô álífábëêtì Yorùbá sára pátákó ìkõwé láti A – K
Kô bí a śe ń śêdá õrõ pêlú álífábëêtì náà.
Àpççrç A- ajá, B – bàtà, D – dòjé, Ç – çyç abbl
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
- Kô álífábëêtì Yorùbá láti A – K sí ara pátákó
- Ka àwôn àpççrç õrõ tí a śêdá náà sí etígbõö àwôn akëkõö
- Ka àwôn àpççrç náà kí akëkõö máa pèé têlé e
4. Pe akëkõö láti kà á.
AKËKÕÖ
- Fi etí sílê bí olùkö śe ń ka álífábëêtì Yorùbá náà
- Śe ìdámõ àwôn õrõ tí a śêdá náà lára pátákó
- Ka têlé olùkö bí ó śe ń kà á.
OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
- Pátákó ìkõwé
- Káàdì aláfihàn
ÕSÊ 4
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
SÍŚÊDÁ ÕRÕ PÊLÚ ÁLÍFÁBËÊTÌ (L – Y)
ÀKÓÓNÚ IŚË
1. Kíkô álífábëêtì Yorùbá sára pátákó ìkõwé láti L – Y.
2. kíkö bí a śe ń śêdá õrõ pêlú álífábëêtì náà. Àpççrç; L – Labalábá, M – Màlúù abbl
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
1. Kô álífábëêtì Yorùbá láti L – Y sí ara pátákó
2. Ka àpççrç àwôn õrõ tí a śêdá náà sí etígbõö àwôn akëkõö
3. Ka àpççrç àwôn náà kí akëkõö máa pè é têlé e
4. Pe akëkõö láti kà á têlé e.
AKËKÕÖ
1.Fi etí sílê bí olùkö śe ń kà á.
2.Śe ìdámõ àwôn õrõ tí a śêdá náà lára pátákó
3.kà á têlé olùkö bí ó śe ń kà á.
OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
•Pátákó Ìkõwé
ÕSÊ 5
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
ÒÝKÀ YORÙBÁ: 1 – 10
ÀKÓÓNÚ IŚË
1. Kín ni òýkà?
2. Ìlò òýkà
3. Kíka òýkà
4. Śíśe ìdámö fígõ òýkà
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
1. Śàlàyé ohun tí òýkà jë
2. Tö akëkõö sönà láti ka òýkà
3. pe akëkõö láti töka sí fígõ òýkà
AKËKÕÖ
1. Tëtí sí àlàyé olùkö lórí òýkà àti ìwúlò rê.
2. ka oókan títí dé çëwàá
3. Da òýkà tí a kô sójú pátákó/ káàdì pélébé mô ni õkõõkan
OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
1. kádíböõdù tí a kô òýkà oókan dé çëwàá sí
2. káàdì pélébé pélébé tí a kô òýkà kõõkan sí
3. àwôn ohun tó śe é kà ìdérí ìgò ôtí, òkúta, ôsàn, igi wëwë, igi ìsáná abbl.
ÕSÊ 6
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
MÍMÔ ÊYÀ ARA
ÀKÓÓNÚ IŚË
1.kíka àwôn êyà ara wa. Àpççrç ojú, orí, etí, apá abbl
2.Orin kíkô nípa êyà ara wa.
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
- Ka êyà ara wa sí etígbõö àwôn akëkõö
- Ka êyà ara náà kí akëkõö máa pè é têlé e
- Pe akëkõö láti fôwö kan êyà ara kõõkan
AKËKÕÖ
- Fi etí sílê bí olùkö śe ń kà á.
- kà á têlé e olùkö bí ó śe ń kà á
- śe idámõ àwôn êyà ara kõõkan
OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
Àwòrán ènìyàn tí a yà sára pátákó.
Kádíböõdù tí a ya àwòrán ènìyàn sí láti śe àpèjúwe êyà ara.
ÕSÊ 7
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
ÌMÖTÓTÓ ARA ÇNI
ÀKÓÓNÚ IŚË
- ìtöjú ara
- ohun èlò ìtöjú ara. Àpççrç (a) ôsç ìfôyín
(b) ìpara abbl.
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
- Śe àlàyé lórí ìmötótó
- Fi orin àti ewì tó jçmö imötótó fa pàtàkì rê yô fún akëkõö
- Śàlàyé bí a śe lè töjú ara çni
- Sô àwôn ohun èlò itöjú ara çni
AKËKÕÖ
- Kô orin àti ewì tó jçmö ìmötótó.
- Sô àwôn ewu tí àitöjú ara lè fà
- Śàlàyé bí a śe lè töjú ara çni
OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
Ìyàrí, ìyarun, kóòmù, bíléèdì, pákò, ôsç, kàìnkàìn, abbl
ÕSÊ 8
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
ÌTÊSÍWÁJÚ LÓRÍ ÌMÖTÓTÓ ARA ÇNI
ÀKÓÓNÚ IŚË
i. Bí a śe ń lo ohun èlò kõõkan fún ìtöjú ara
ii. Ewu tí ó wà nínú àìtöjú ara çni
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
1. Śàlàyé bí a śe lè töjú ara çni
2. Śàlàyé bí a śe ń lo àwôn ohun èlò ìtöjú
ara wõnyí lëyô kõõkan
3. Śàlàyé àwôn ewu tó wà nínú àìtöjú ara çni.
AKËKÕÖ
1. Śàlàyé bí a śe lè töjú ara çni
2. Sô ewu tó wà nínú àìtöjú ara çni
3. Kópa nínú śíśe ìtöjú ara.
OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
Löfíndà, bíléèdì, ôsç ìfôyín.
Àwòrán tó ń fi çni tó ń wê ní balùwê hàn.
ÕSÊ 9
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
ÌSÕRÕÝGBÈSÌ
ÀKÓÓNÚ IŚË
Bíbéèrè ìbéèrè láti õdõ akëkõö sí olùkö Láàrin akëkõö sí ara wôn
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
1.Tö akëkõö sönà láti lè dáhùn àwôn ìbéèrè náà bí ó ti tö.
2.Jë kí akëkõö béèrè ìbéèrè löwö ara wôn
AKËKÕÖ
Fún olùkö ní ìdáhùn tó bá ìbéèrè olùkö mu.
OHUN-ÈLÒ ÌKÕNI
Śíśe àmúlò àwôn akëkõö láti béèrè ìbéèrè löwö ara wôn.
ÕSÊ 10
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
ORIN ERÉ ÌDÁRAYÁ
ÀKÓÓNÚ IŚË
Orin eré ìdárayá. Àpççrç “çyç mëta wáyé
tolongo” abbl
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
1. Śe àlàyé lórí eré ìdárayá
2. kô oríśiríśi àwôn eré ìdárayá tí ó wà.
3. Śàlàyé àkókò tí a máa ń śe eré ìdárayá
4. Kô orin àti ewì tí ó jçmö eré ìdárayá
AKËKÕÖ
1. Kô orin eré idaraya
2. Kópa nínú eré ìdárayá
3. Śàlàyé bí a śe ń śe õkõõkan wôn
OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
Àwòrán àwôn akëkõö láti béèrè ìbéèrè löwö ara wôn.
ÕSÊ 11
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
ÌWÀ RERE
ÀKÓÓNÚ IŚË
i.Kín ni à ń pè ní ìwà rere?
ii.Báwo ni a śe lè dá ômôlúàbí mõ.
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
1.Sô oríśiríśi õnà tí a lè fi jé oníwà rere
2.Töka sí àwôn ìwà tí kò fi ìwà rere hàn
3.Kô orin aköniníwà fún akëkõö
4.Sô èrè tàbí àýfààní tó wà nínú kí ènìyàn jë oníwà rere
AKËKÕÖ
1.Fetí sí àlàyé nípa ìwà rere
2.Kópa nínú kíkô oríśiríśi orin aköniníwà
3.Sô àwôn àýfààní jíjë oníwà rere.
OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
1.Fídíò àti kásëëtì tó ń köni ní ìwà rere
2.Àwòrán tó ń śàfihàn ibõwõfágbà
3.Téèpù àti kásëêtì tí a gba orin akömô níwà sí
ÕSÊ 12
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
ÌGBÀ NÍNÚ ÔDÚN
ÀKÓÓNÚ IŚË
Àwôn ìgbà tó wà nínú ôdún: ìgbò òjò, ìgbà êêrùn, ìgbà oorun, ôyë abbl
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
- śàlàyé ohun tí ìgbà ôdún jë
- kô àwôn ìgbà ôdún náà ní orin
- pe akëkõö láti sô ohun tí à ń pè ní ìgbà ôdún.
AKËKÕÖ
- Tëtí sí àlàyé olùkö lórí ôdún kõõkan
- ka ìgbà ôdún náà láti orí
OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
Àwòrán òjò tó ń rõ
ÕSÊ 13: ÀTÚNYÊWÒ ÊKÖ
ÕSÊ 14: ÌDÁNWÒ
Nigeria Language Syllabus, Yoruba Language scheme of work primary 1 Federal, álífábëêtì Yorùbá, Orin eré ìdárayá.
SECOND TERM SCHEME OF WORK FOR YORUBA LANGUAGE PRIMARY 1
YORÙBÁ PRIMARY 1 TÁÀMÙ KEJÌ
ÕSÊ 1
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
ÌTÊSÍWÁJÚ LÓRÍ ÌMÖTÓTÓ
ÀKÓÓNÚ IŚË
- ìtöjú àyíká ilé-çni
- Ìtöjú àyíká ilé-ìwé àti gbígbá àyíká
- Kíkô orin tí ó bá ìmötótó lô
- Gbíngbin òdòdó sí àyíká wa
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
- Śe àlàyé ní êkúnrërë nípa ìmötótó ní àyíká ilé àti ilé-êkö.
- Fi àwôn ohun èlò fún ìmötótó ilé àti àyíká hàn
- kô orin tí àìtöjú àyíká çni lè fà
- Tö akëkõö sönà láti śe àkíyèsí àyíká kí wön sì śe àtúnśe rê
AKËKÕÖ
- Sô bí a śe lè śe ìmötótó àyíká wa
- sô àwôn ewu tí àìtöjú àyíká le fà
- kô orin àti ewì ìmötótó
- kópa nínú títún àyíká śe
OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
- Ìgbálê
- ôkö
- àdá
- réèkì
- apêrê ìdalê-nù
- ìkólê
ÕSÊ 2
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
KÍKÔ ÁLÍFÁBËÊTÌ ÈDÈ YORÙBÁ
ÀKÓÓNÚ IŚË
1. Kíkô álífábëêtì Yorùbá elégeé sí ara pátákó
2. Dídá álífábëêtì kõõkan mõ, àpççrç – A B D E Ç abbl
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
1. Tó álífábëêtì Yorùbá elégèé sí ara pátákó
2. Pe akëkõö láti fi çfun kô álífábëêtì Yorùbá elégèé tí olùkö kô sí ojú pátákó
AKËKÕÖ
1. fi etí sílê bí olùkö śe ń ka álífábëêtì Yorùbá náà
2. pè é têlé olùkö
3. fi çfun/ pëńsù tó àwôn lëtà álífábëêtì Yorùbá náà.
OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
Kádíböõdù pélébé pélébé tí a kô álífábëêtì Yorùbá elégèé sí
ÕSÊ 3
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
DÍDÁ NÝKAN INÚ KÍLÁÁSÌ MÕ
ÀKÓÓNÚ IŚË
Mímô ohun tí ó wà nínú kíláásì bí i àga,
tábìlì, pátákó ìkõwé, àwòrán ara ògiri abbl
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
1. Darí akëkõö láti śe ìdámõ àwôn nýkan tó wà nínú kíláásì
2. Tö wôn sönà láti dárúkô àwôn nýkan náà
AKËKÕÖ
- Dídá ohun tó wà nínú kíláásì mõ
- Dídárúkô àwôn nýkan náà
OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
Àwôn ohun tó wà nínú kíláásì bí i: àga, tábìlì, pátákó ìkõwé, àwòrán ara ògiri, ìwé, çfun ìkõwé abbl.
ÕSÊ 4
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
MÍMÔ OHUN TÍ Ó WÀ NÍ ÀYÍKÁ – ILÉ- ÌWÉ
ÀKÓÓNÚ IŚË
Orúkô àwôn nýkan tí ó wà ní àyíká: Bëêdì, òdòdó, ewúrë, igi, àga, amóhúnmáwòrán, ilê, ôkõ abbl
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
- pe akëkõö láti dárúkô àwôn ohun tí ó wà ní àyíká rç.
- sô ìwúlò àwôn ohun tí ó wà ní àyíká
- pe akëkõö láti fi àwôn ohun tí ó wà ní àyíká wôn kôrin
AKËKÕÖ
- Dárúkô ohun tí ó wà ní àyíká rç
- Sô ìwúlò wôn
- fi àwôn ohun tí ó wà ní àyíká kô orin
- OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
Àwòrán àwôn ohun tó wà ní àyíká tàbí nýkan náà gan-an.
ÕSÊ 5
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
MÍMÔ NÝKAN TÍ Ó WÀ NÍ ÀYÍKÁ
ÀKÓÓNÚ IŚË
Àwôn orúkô nýkan tó wà ní àyíká akëkõö
Ilé – tçlifísàn, rédíò, bëêdì, àga abbl
Ilé-ìwé – çfun, aga àti tábìlì, rúlà, bírò abbl
Ôjà – ata, iśu, èso, èlùbö, çran abbl
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
1. Pe olùkö láti dárúkô àwôn ohun tí ó wà ní àyíká rê
2. sô ìwúlò tàbí àýfààní wôn
3. pe akëkõö láti fi àwôn ohun tí ó wà ní àyíká wôn kô orin
AKËKÕÖ
1. Dárúkô àwôn ohun tí ó wà ní àyíká rç.
2. Sô ìwúlò àwôn ohun tí ó wà ní àyíká rç
3. Fi àwôn ohun tó wà ní àyíká wôn kôrin/ śeré
OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
Àwòrán àwôn ohun tó wà ní àyíká tàbí àwôn nýkan náà gan-an
ÕSÊ 6
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
ŚÍŚE NÝKAN
ÀKÓÓNÚ IŚË
Pípa àśç – àpççrç Dìde, jókòó, dúró, wá,
jáde, wôlé, dákë, pàtëwö abbl
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
Olùkö tö akëkõö sönà pé kí wön dìde, dúró, jókòó, wôlé, wá, jáde pàtëwö abbl
AKËKÕÖ
Śe àwôn ohun tí olùkö ní kí o śe
OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
1. Śíśe àmúlò àwôn akëkõö
2. Àwôn nýkan inú kíláásì
ÕSÊ 7
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
ÒÝKÀ YORÙBÁ (11 – 20) – Óókànlá dé ogún
ÀKÓÓNÚ IŚË
1. Òýkà láti óókànlá dé ogún
2. Śíśe ìdámõ fígõ óókànlá dé ogún
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
1. Tö akëkõö sönà láti ka òýkà láti ôökànlá dé
ogún
2. Pe akëkõö láti śe ìdámõ fígõ òýkà láti ôökànlá dé ogún
AKËKÕÖ
1. Tëtí sí àlàyé olùkö lórí òýkà láti ôökànlá dé ogún
2. Ka òýkà láti ôökànlá dé ogún
3. Dá òýkà tí a kô sí ojú pátákó/ ìwé pélébé pélébé mõ ní õkõõkan.
OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
Kádíböõdù àti ìwé pélébé pélébé tí a kô òýkà kõõkan sí láti ôökànlá dé ogún
ÕSÊ 8
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
ÔJÖ INÚ ÕSÊ
ÀKÓÓNÚ IŚË
1. Dídá orúkô ôjö inú õsê mõ: Sunday –
Àìkú, Monday – Ajé, Tuesday – Ìśëgun abbl
2. Sô di orin – Àiku ajé ìśëgun ôjörú ôjöbõ çtì àbámëta.
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
1. Śàlàyé ohun tí ôjö jë
2. Kô àwôn ôjö náà ní orin
3. Pe akëkõö láti sô òun tí a pe ôjö Monday abbl ní èdè Yorùbá.
AKËKÕÖ
1. Tëtí sí àlàyé olùkö lórí ôjö kõõkan
2. Ka ôjö náà láti àìkú dé àbámëta
3.Kô àwôn ôjö náà ni orin.
OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
•Kádíböõdù pélébé pélébé tí a kô ôjö kõõkan sí.
ÕSÊ 9
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
ÌTÊSÍWÁJÚ LÓRÍ ÔJÖ INÚ ÕSÊ
ÀKÓÓNÚ IŚË
1. Àlàyé àti ìtàn nípa ôjö kõõkan:
i. Ôjö Àìkú jë ôjö ayõ ó dára láti śe ohun rere.
ii. Ôjö Ajé – ôjö rere láti bêrê òwò śíśe tàbí ôjà títà, Ilé kíkö.
2. Kíkô ní orin.
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
1. Śàlàyé ìtumõ àwôn ôjö wõnyí
2. Pe akëkõö láti sô ìtumõ ôjö kõõkan
AKËKÕÖ
1. Tëtí sí àlàyé olùkö lórí ôjö kõõkan
2. Pè wön têlé olùkö.
OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
Kádíböõdù pélébé pélébé tí a kô ôjö kõõkan sí.
ÕSÊ 10
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
ÒÝKÀ OWÓ NÁÍRÀ
ÀKÓÓNÚ IŚË
- Àlàyé lórí kíka owó náíra
- Ìlò owó náírà
- Śíśe idámõ owó náírà kõõkan
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
1.Śàlàyé ohun tí owó náíra jë
2.Tö akëkõö sönà láti ka owó náírà
3.Pe akëkõö láti töka sí owó náírà
AKËKÕÖ
1.Tëtí sí àlàyé olùkö lórí owó náírà
2.Ka iye owó náírà
3.Dá iye owó náírà kõõkan mõ
OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
Śíśe àfihàn owó náírà kõõkan
ÕSÊ 11: ÀTÚNYÊWÒ ÊKÖ
ÕSÊ 12: ÌDÁNWÒ
Nigeria Language Syllabus, Yoruba Language scheme of work primary 1 Federal, álífábëêtì Yorùbá
THIRD TERM SCHEME OF WORK FOR YORUBA LANGUAGE PRIMARY 1
ÕSÊ 1
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
ÌKÍNI: Ìkíni ní onírúurú ìgbà
ÀKÓÓNÚ IŚË
1. Ìkíni ní onírúurú ìgbà tó wà nínú ôdún. Ìkíni ní ìgbà òjò, ìgbà êrùn tàbí õgbçlê, ìkíni ní ìgbà ôyë abbl. B.a, Ç kú òjò, ç kú õgbçlê, ç kú ôyë
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
- Darí akëkõö láti fi bí a śe ń kí ni śeré
- Fi àwòrán àwôn tó ń kí ara wôn han akëkõö
AKËKÕÖ
- Sô ohun tí wôn mõ nípa àśà ìkíni sáájú ìdánilëkõö.
- Śe àpççrç àwôn oríśi ìkíni tí wôn ti gbö rí sáájú ìdánilëkõö
- kópa nínú eré bí a śe ń kí ni
OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
Àwòrán àwôn tó ń kí ara wôn.
ÕSÊ 2
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
ÌWÀ RERE
ÀKÓÓNÚ IŚË
- Kín ni à ń pè ní ìwà rere tàbí ômôlúàbí?
- Báwo ni a śe lè dá ômôlúàbí mõ? Àpççrç – ìsòdodo, sùúrù, õyàyà, ìmúra, ìkónimöra, ìwà pêlë abbl.
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
- Lo ewì, owe, àśàyàn õrõ, orin àti ìtàn láti fi töka sí àýfààní tí ó wà nínú ìwà rere. B.a “Töjú Ìwà rç õrë mi”.
- Śàlàyé ojúśe ômôlúàbí sí òbí, ômônìkejì, ìjôba, àwùjô
Ìśòro tí ômôlúàbí lè dojú kô àti bí ó śe le borí rê
AKËKÕÖ
- Sô àpççrç ìwà ômôlúàbí
- Sô àýfààní tó wà nínú híhu ìwà bëê.
- Sô àpççrç ìwà tó lòdì sí ìwà ômôlúàbí àti ewu tí irú ìwà bëê lè fà.
- Sô wàhálà tí ó lè dé bá ômôlúàbí àti bí òótö inú śe le kó o yô.
OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
- Fídíò àti kásëêtì tó ń kö ni ní ìwà rere
- Téèpù àti kásëêtì tí a gba orin akömôníwà sí.
ÕSÊ 3
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
ÌTÊSÍWÁJÚ LÓRÍ ÌWÀ RERE
ÀKÓÓNÚ IŚË
Ìbõwõ fágbà:- kíkö nípa bí a śe ń bá àgbà sõrõ, dídõbálê, kíkúnlê abbl
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
1. Sô oríśiríśi õnà tí a lè fi jë oníwà rere
2. Töka sí àwôn ìwà tí ó fi ìwà rere hàn
3. sô èrè tàbí àýfààní tó wà nínú kí ômôdé bõwõ fágbà
AKËKÕÖ
1. Fetí sí àlàyé nípa ìwà rere
2. Sô àwôn àýfààní jíjë oníwà ìrêlê
OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
Àwòrán tó ń śàfihàn ìbõwõfágbà
ÕSÊ 4
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
OJÚŚE (ÇBÍ SÍ ÌDÍLÉ)
ÀKÓÓNÚ IŚË
1. kín ni ojúśe?
2. ojúśe çnìkõõkan nínú ìdílé – ômô sí òbí, êgbön sí àbúrò, òbí sí ômô.
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
1.Sô ìtumõ ojúśe
2.Śàlàyé ojúśe çnìkõõkan nínú ìdílé
3.Jë kí akëkõö fi ìbõwõ fágbà òbí śeré
AKËKÕÖ
1.Sô ìtumõ têlé olùkö
2.Sô ojúśe rê gëgë bí ômô nínú ilé.
3.Kópa nínú eré.
OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
•Àwôn akëkõö gan-an kí wôn kópa nínú eré ìbõwõ fún òbí àti çni tí ó ju ú lô.
ÕSÊ 5
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
ÌTÊSÍWÁJÚ LÓRÍ OJÚŚE (ÇBÍ ÀTI ÌDÍLÉ)
ÀKÓÓNÚ IŚË
1. Ojúśe ômô nínú ilé – bí àpççrç; fô abö, jë iśë tí wôn bá rán-an.
2. Òbí sí ômô, b.a san owó ilé-ìwé, ra aśô fún ômô, pèsè ìwòsàn nígbà àìsàn, wá oúnjç abbl
3. Êgbön sí àbúrò – śe ìtöjú àbúrò rê, dáàbòbò ó abbl
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
1. Sô ìtumõ ojúśe
2.Śàlàyé ojúśe òbí sí ômô, ômô sí òbí, êgbön sí àbúrò nínú ìdílé
3.Jë kí akëkõö fi ìbõwõ fún òbí śeré
AKËKÕÖ
1. Sô ìtumõ têlé olùkö
2. Sô ojúśe rç gëgë bí ômô nínú ilé
3. Kópa nínú eré
OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
Àwòrán ômô tí ó ń gbálê nínú ilé.
ÕSÊ 6
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
ÌSÕRÕÝGBÈSÌ LÁÀRIN AKËKÕÖ
ÀKÓÓNÚ IŚË
1. Ìbánisõrõ láàrin akëkõö méjì lórí bíbéèrè orúkô ara wôn àti orúkô òbí wôn.
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
1. Tö akëkõö sönà láti lè dáhùn àwôn ìbéèrè náà bí ó ti tö
2. Jë kí akëkõö béèrè ìbéèrè löwö ara wôn.
AKËKÕÖ
Fún olùkö ní àwôn ìdáhùn tó bá ìbéèrè olùkö mu.
OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
Śíśe àmúlò akëkõö láti béèrè ìbéèrè löwö ara wôn.
ÕSÊ 7
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
ORÍŚIRÍŚI ÈSO, OÚNJÇ ÀTI EWÉBÊ
ÀKÓÓNÚ IŚË
• Dídárúkô oríśiríśi èso òrombó, õgêdê, àgbálùmõ abbl.
• Oúnjç: ìrçsì, êwà, iśu, gààrí abbl
• Ewébê: êfö, amúnútutù, ewédù, êfö têtê abbl
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
1. Pe akëkõö láti dárúkô àwôn èso, oúnjç àti ewébê.
2. Sô ìwúlò àti iśë tí àwôn èso, oúnjç àti ewébê ń śe ara
AKËKÕÖ
1. Dárúkô àwôn èso, oúnjç àti ewébê tí ó wà ní agbègbè.
2. Sô ìwúlò àti iśë tí àwôn èso, oúnjç àti ewébê ń śe
OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
Àwòrán àwôn igi eléso, oúnjç àti ewébê.
ÕSÊ 8
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
SÁÁJÚ KÍKÔ ÁLÍFÁBËÊTÌ YORÙBÁ
ÀKÓÓNÚ IŚË
1. Kíkô fáwëlì àti köńsónáýtì èdè Yorùbá b, d, f, g, gb, h, j, k, l, m, n, p, r, s, ś, t, w, y.
2. Fáwëlì àìránmúpè: a, e, ç, i, o, ô, u.
3. Fáwëlì aránmúpè: an, ôn, çn, un, in.
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
1. Kô álífábëêtì Yorùbá sókè fún àwôn akëkõö
2. Kô àwôn lëtà tí ó dúró fún ìró õrõ köńsónáýtì, fáwëlì àìránmúpè lötõõtõ sójú pátákó.
3. Pè wön lökõõkan fún akëkõö köńsónáýtì
AKËKÕÖ
1. Śe àwòkô àtç álífábëêtì Yorùbá
2. Śe àwòkô àwôn lëtà ìró köńsónáýtì, fáwëlì àìránmúpè àti àránmúpè.
3. Pe àwôn fáwëlì àti köńsónáýtì náà bí olùkö śe pè wön.
OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
1. Kádíböõdù ńlá tí a kô álífábëêtì Yorùbá sí.
2. Káàdì pélébé pélébé tí a kô àwôn lëtà náà sí.
ÕSÊ 9
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
ÌMÕLÁRA AKËKÕÖ LÁSÌKÒ TÍ A WÀ
ÀKÓÓNÚ IŚË
- Ooru mú mi – ìgbà oorùn
- Otútù mú mi – ìgbà òjò tàbí ìgbà ôyë abbl
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
- Pe akëkõö láti sô ìmõlára rê ní àkókò tí ó wà
- Bíbéèrè löwö akëkõö ohun tí ó śe é tí ojú rê fi körë löwö.
AKËKÕÖ
- Sô ohun tí ó śçlê löwö sí i.
- Kópa nínú eré náà
OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
- Àwòrán tó śe àfihàn çni tí ó kájô sí ojú kan náà.
ÕSÊ 10
ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ
ÀRÒKÔ KÉÈKÈÈKÉ
ÀKÓÓNÚ IŚË
- Àròkô nípa oúnjç. Àpççrç; oúnjç tí mo fëràn jù
- Àròkô nípa orúkô ènìyàn
ÀMÚŚE IŚË
OLÙKÖ
1.Tö akëkõö sönà láti jíròrò lórí àkôlé kan tí wön báyàn.
2.Darí akëkõö láti śe ìlapa èrò.
3.Tö akëkõö sönà láti kô àròkô
AKËKÕÖ
1.Jíròrò lórí àkôlé tí a yàn nípa títêlé ìlànà olùkö.
2.Kópa nínú śíśe ìlapa èrò àti àtúntò rê.
3.Lo ìlapa èrò láti kô àròkô.
OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI
•Pátákó çlëmõön tí a kô àkôlé àti ìlapa èrò sí.
ÕSÊ 11: ÀTÚNYÊWÒ ÊKÖ
ÕSÊ 12: ÌDÁNWÒ