Senior Secondary School Humanities Syllabus for Yoruba. SS 3 Yoruba Language Scheme of Work Federal – Schemeofwork.com
YORÙBÁ SS 3 TÁÀMÙ KÌN-ÍN-NÍ
ÕSÊ | ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ | ÀMÚŚE IŚË |
1. | ÀŚÀ: Ìwà Ômôlúàbí ÀKÓÓNÚ IŚË Òtítö sísô, níní sùúrù, ìkíni, ìbõwõ fágbà, śíśe ojúśe nínú ilé, ìwàpêlë, ìgböràn àti bëê bëê lô. | OLÙKÖ a. Sô irú çni tí à ń pè ní ômôlúàbí b. Sô èrè tó wà nínú jíjë ômôlúàbí láwùjô d. Lo òwe, orin, ewì, àśàyàn õrõ àti ìtàn láti fi kö akëkõö nípa adùn tó wà nínú ìwà rere e. Sô ìśòro tí ômôlúàbí lè dojúkô àti bí ó śe lè borí wôn. AKËKÕÖ a. Àwôn ìwà tó ń mú ni jë ômôlúàbí b. Sô àpççr ç ìwà ômôlúàbí d. Àýfààní tó wà nínú híhu ìwà bëê e. Àpççrç ìwà tó lòdì sí ìwà ômôlúàbí ç. Irú ewu tí ìwà bëê lè fà f. Wàhálà tó lè dé bá ômôlúàbí àti bí ó śe lè borí ìśòro yìí. OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI Àwôn ìwé lítírèśõ tó dá lórí ìwà ômôlúàbí Fídíò, fíìmù tó śe eré nípa ìwà ômôlúàbí |
2. | ÀTÚNYÊWÒ LËTÀ ÀÌGBAGBÊFÊ ÀKÓÓNÚ IŚË Rán àwôn akëkõö létí ìgbésê kíkô lëtà àìgbagbêfê Fún àwôn akëkõö ní orí-õrõ lëtà àìgbagbêfê | OLÙKÖ a. Tö àwôn akëkõö sönà láti kô lëtà àìgbagbêfê. b. Kô lëtà sí ilé-iśë rédíò kan nípa ire àti ibi tó wà nínú àśà ìgbàlódé tí àwôn õdö ń kó. AKËKÕÖ a. Sô oríśiríśi lëtà tó wà b. Têlé ìlànà olùkö láti kô lëtà àìgbàgbêfê d. Sô ìyàtõ tó wà láàrin lëtà gbêfê àti àìgbagbêfê OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI Pátákó tí a kô ìlànà lëtà kíkô sí Ìwé àpilêkô lórí àròkô |
3. | ÈDÈ: Ìsõrí õrõ Àkóónú iśë Àlàyé lórí õrõ-àpèjúwe, õrõ-àpönlé, õrõ-atökùn àti õrõ-àsopõ Sísô ipò tí õkõõkan máa ń wà nínú ìhun gbólóhùn | OLÙKÖ a. Sô iśë tí õkõõkan àwôn õrõ wõnyí máa ń śe nínú gbólóhùn b. Kô àpççrç irúfë õrõ wõnyí sókè d. Pe àwôn õrõ náà fún akëkõö AKËKÕÖ a. Dá àwôn ìsõrí õrõ yìí mõ nínú ìhun gbolohun b. Pe àwôn õrõ náà bí olùkö śe pè wön. d. Śe àwòkô àwôn õrõ tí olùkö kô sójú pátákó. OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI Kádíböõdù pélébé pélébé tí a kô àpççrç àwôn ìsõrí õrõ sí. Ìwé atúmõ èdè Yorùbá Pátákó ìkõwé àti çfun. |
4. | LÍTÍRÈŚÕ:Kíkö ni mímõ:Iśë Òýkõwé Alátinúdá (Ewì, ìtàn àròsô, eré-onítàn) ÀKÓÓNÚ IŚË Àtúnyêwò àwôn ìlànà tí òýkõwé ní láti kíyèsí fún kíkô ìwé alátinúdá Gbígbìyànjú láti kô ewì, ìtàn àròsô àti eré-onítàn kékèèké | OLÙKÖ a. Śe àlàyé kíkún lórí kíkô ìwé alátinúdá. b. Sô ìlànà ìgbékalê ìwé alátinúdá d. Sô àwôn èròjà tó mú kí ìwé dùn e. Jë kí akëkõö gbìyànjú àtikô ìwé àtinúdá ç. Pípe àwôn gbajúmõ òýkõwé láti wá dá akëkõö lëkõö AKËKÕÖ a. Tëtí sí àlàyé olùkö lórí kíkô ewì àtinúdá: ìlànà ìgbékalê, àtinúdá àti èròjà tó ń mú adùn bá ewì b. Tëtí sí ìdánilëkõö láti õdõ gbajúmõ òýkõwé d. Kô eré-onítàn àti ewì kékèèké. OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI Ìwé ìtàn àròsô Ìwé eré-onítàn Ìwé ewì |
5. | ÀŚÀ: Ètò Çbí ÀKÓÓNÚ IŚË Àlàyé lórí ohun tí à ń pè ní çbí Bàbá gëgë bí olórí çbí d. Iśë òbí sí ômô àti iśë ômô sí òbí e. Ìbáśepõ láàrin ômô ìyá sí ômô ìyá àti ôbàkan sí ôbàkan. ç. Ìbáśepõ pêlú ìdílé ìyá çni àti bàbá çni f. Ipò àti iśë tí çnìkõõkan ń śe nínú çbí. | OLÙKÖ a. Sô oríkì çbí b. Śàlàyé kíkún lórí ojúśe çnìkõõkan nínú çbí d. Kô kókó pàtàkì pàtàkì sójú pátákó AKËKÕÖ a. Tëtí sí àlàyé olùkö b. Béèrè ìbéèrè löwö olùkö d. Dáhùn ìbéèrè olùkö e. Śe àkôsílê ohun tí olùkö kô sí ojú pátákó OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI Àwòrán FídíòTçlifísànTéèpù |
6. | ÈDÈ: Aáyan Ògbufõ ÀKÓÓNÚ IŚË a. Ìtönisönà lórí bí a śe ń śe aáyan ògbufõ. b. Túmõ àwôn õrõ àti èdè ewì láti èdè Gêësì sí Yorùbá. | OLÙKÖ a. Śàlàyé bí a śe ń śe aáyan ògbufõ b. Darí akëkõö láti túmõ àwôn õrõ àti èdè ewì tí a kô sójú pátákó láti èdè Gêësì sí èdè Yorùbá d. Kô àwôn õrõ àti ewì tí a túmõ sí ojú pátákó. AKËKÕÖ a. Tëtí sí bí olùkö śe ń túmõ àwôn õrõ àti ewì. b. Túmõ àwôn õrõ tí olùkö fún un sí èdè Yorùbá. d. Kô àwôn ohun tí olùkö kô sí ojú pátákó sí inú ìwé. OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI Ìwé tí a yànÌwé atúmõPátákó ìkõwé |
7. | LÍTÍRÈŚÕ: EwìÀpilêkô ÀKÓÓNÚ IŚË Kókó õrõ Ìhun (ètò) d. Ìlò èdè e. Àśà àti ìśe tí ó súyô ç. Àmúyç àti àléébù inú rê | OLÙKÖ a. Jë kí akëkõö ka àśàyàn ewì tí ó mõ b. Jë kí akëkõö ka àśàyàn ewì síta d. Śàlàyé nípa àkóónú iśë bí ó śe súyô nínú ewì Kókó õrõ Ìhun Ìlò èdè Àśà tó súyô Àmúyç àti àléébù e. Kô àwôn õrõ tí ó śe pàtàkì tí ó súyô sójú pátákó pêlú àlàyé ìtumõ wôn OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI Àśàyàn ìwé àpilêkô Pátákó ìkõwé. |
8. | Ìtêsíwájú Eré Ìdárayá ÀKÓÓNÚ IŚË a. Oríśiríśi eré ìdárayá Eré òśùpá, bojúbojú…Eré abëlé – àlô pípaEré ìta gbangba, òkòtó títa, àrìn títa, ìjàkadì/ çkç àti bëê bëê lô b. Eré òde òní Böõlù gbígbáEré sísáDíráfítì títaKáàdì títaLúdò àti bëê bëê lô | OLÙKÖ a. Śàlàyé bí a ti ń śe díê nínú eré ìdárayá tí a mënubà b. Tö akëkõö sönà láti śe àwôn eré ìdárayá náà d. Kô àwôn orin inú eré ìdárayá tó lórin sójú pátákó e. Tö akëkõö sönà láti sô àwôn àýfààní àti ewu tí ó wà nínú eré náà AKËKÕÖ a. Tëtí sí àlàyé olùkö b. Sô ohun tí o mõ nípa eré ìdárayá śáájú ìdánilëkõö d. Kópa nínú śíśe eré ìdárayá náà e. Béèrè ìbéèrè ç. Śe àkôsílê ohun tí olùkö kô sójú pátákó sínú ìwé OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI Àwòrán ohun èlò gidi: ôpön ayò, lúdò, díráfíìtì àti bëê bëê lô Àwòrán agbáböõlù àti bëê bëê lô |
9. | ÌTÊSÍWÁJÚ LÓRÍ ÀRÀNMÖ ÀKÓÓNÚ IŚË a. Oríkì àrànmö b. Àrànmö ohùn d. Àrànmö Fáwëlì e. Àrànmö iwájú ç. Àrànmö êyìn f. Àrànmö aláìfòró àti àrànmö afòró | OLÙKÖ a. Śàlàyé fún àwôn akëkõö ohun tí àrànmö jë b. Sô oríśiríśi àrànmö tí ó wà pêlú àpççrç tí ó múná dóko d. Béèrè ìbéèrè löwö akëkõö e. Śe àkôsílê sójú pátákó AKËKÕÖ a. Tëtí sí olùkö b. Béèrè ìbéèrè löwö olùkö d. Dáhùn ìbéèrè olùkö e. Śe àkôsílê sínú ìwé rç OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI Pátákó ìkõwé |
9. | ÌTÊSÍWÁJÚ LÓRÍ ÀRÀNMÖ ÀKÓÓNÚ IŚË a. Oríkì àrànmö b. Àrànmö ohùn d. Àrànmö Fáwëlì e. Àrànmö iwájú ç. Àrànmö êyìn f. Àrànmö aláìfòró àti àrànmö afòró | OLÙKÖ a. Śàlàyé fún àwôn akëkõö ohun tí àrànmö jë b. Sô oríśiríśi àrànmö tí ó wà pêlú àpççrç tí ó múná dóko d. Béèrè ìbéèrè löwö akëkõö e. Śe àkôsílê sójú pátákó AKËKÕÖ a. Tëtí sí olùkö b. Béèrè ìbéèrè löwö olùkö d. Dáhùn ìbéèrè olùkö e. Śe àkôsílê sínú ìwé rç OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI Pátákó ìkõwé |
10. | ÀTÚNYÊWÒ ÈTÒ ÌŚÈLÚ ÀKÓÓNÚ IŚË Ààtò agbo-ilé Ètò oyè jíjç · oyè ìdílé · Oyè ìfidánilölá d. Ètò ìśèlú òde òní: · Ìjôba àpapõ · Ìjôba ìpínlê Ìjôba ìbílê | OLÙKÖ a. Śàlàyé ààtò agbo-ilé b. Śàlàyé ní kíkún lórí oyè jíjç àti oríśiríśi tó wà d. Sô nípa ìśèlú òde òní fún àwôn akëkõö AKËKÕÖ a. Sô àwôn tó ń kópa nínú àtò agbo-ilé b. Sô ipa akópa kõõkan tí wön dárúkô ní (a) d. Sô oríśiríśi oyè tí ó wà ní àwùjô e. Śàlàyé ìjôba àpapõ àti ìbílê OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI Fídíò ayçyç ìfinijoyè |
11. | LÍTÍRÈŚÕ: Àtúpalê àśàyàn ìwé ìtàn àròsô méjì ÀKÓÓNÚ IŚË Kókó õrõ Àhunpõ ìtàn d. Ìfìwàwêdá e. Ibùdó ìtàn ç. Ôgbön ìsõtàn f. Àśà tí ó súyô g. Àmúyç àti àléébù | OLÙKÖ a. Mójú tó àwôn akëkõö láti kàwé ìtàn àròsô b. Śàlàyé àhunpõ ìtàn, ìfìwàwêdá, ibùdó ìtàn, ôgbön ìsõtàn àti ti àśà tó súyô. d. Jíròrò pêlú akëkõö láti sô àmúyç àti àléébù inú àwôn ìtàn tí wön kà. AKËKÕÖ a. Ka ìwé ìtàn àròsô méjèèjì b. Śe àtúnsô ìtàn inú ìwé ìtàn àròsô tí wön kà ní sókí d. Jíròrò lórí ìfìwàwêdá, ibùdó ìtàn àti ôgbön ìsõtàn. e. Sô àwôn àśà tó súyô nínú ìtàn tí wôn kà. OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI Ìwé ìtàn àròsô tí a yàn Àwòrán tí ó bá lè jëwö ìśêlê inú ìwé ìtàn àròsô tí a yàn. |
12. | ÌTÊSÍWÁJÚ LÓRÍ ÌGBÉYÀWÓ, ÌSÌNKÚ ÀTI OGÚN JÍJÇ ÀKÓÓNÚ IŚË a. Àtúnyêwò ìsìnkú ìbílê b. Ìsìnkú ômôlëyìn Kírísítì, Mùsùlùmí àti bëê bëê lô d. Àtúnyêwò ogún jíjç ní ìlànà ìbílê e. Ogún jíjç ní ìlànà ìgbàlódé | OLÙKÖ a. Jíròrò pêlú àwôn akëkõö lórí ìsìnkú ìbílê b. Śàlàyé ìsìnkú ômôlëyìn Kírísítì, Mùsùlùmí àti bëê bëê lô d. Śàlàyé ogún jíjç ní ìlànà ìbílê e. Śàlàyé ogún jíjç ìgbàlódé AKËKÕÖ a. Śe àbêwò sí ibi ìsìnkú ìbílê b. Śe àbêwò síbi ìsìnkú ômôlëyìn Kírísítì àti ti Mùsùlùmí d. Śe ìròyìn ojúmi to fún àwôn çlçgbë wôn lórí àbêwò wôn sí irúfë ìsìnkú mëtêêta. OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI Àwòrán ìjókòó àwôn àgbà níbi tí wön ti ń pín ogún Àwòrán àwôn tó gbé òkú tí wön ń tu adìyç ìrànà níwájú rê. Fídíò ìsìnkú àti àsìkò ogún pínpín. |
13. | ÀTÚNYÊWÒ ÊKÖ | |
14. | ÌDÁNWÒ |
Senior Secondary School Humanities Syllabus for Yoruba. SS 3 Yoruba Language Scheme of Work Federal – Schemeofwork.com
YORÙBÁ SS 3 TÁÀMÙ KEJÌ
ÕSÊ | ORÍ ÕRÕ/ ÀKÓÓNÚ | ÀMÚŚE IŚË |
1. | ÈDÈ: Àtúnyêwò gbogbo ìsõrí gbólóhùn, ìpàrójç àti ìsúnkì ÀKÓÓNÚ IŚË a. Gbólóhùn abödé, gbólóhùn oníbõ, alálàyé, ìbéèrè àti àśç, gbólóhùn alákànpõ, oníròyìn, alátçnumö àti gbólóhùn ìyísódì b. Oríkì ìpajç, òfin ìpajç, fáwëlì àti köńsónáýtì pípajç d. Ìyöpõ fáwëlì e. Oríkì ìsúnkì ç. Ìbáśepõ tí ó wà láàrin ìpajç àti ìsúnkì. | OLÙKÖ a. Śàlàyé oríśiríśi ìsõrí gbólóhùn b. Śàlàyé ìyàtõ tí ó wà láàrin gbólóhùn kõõkan d. Sô oríkì ìpajç, ìsúnkì àti ìyöpõ fáwëlì e. Sô òfin tí ó de ìpajç, ìsúnkì àti ìyöpõ fáwëlì ç. Béèrè ìbéèrè löwö akëkõö f. Yán kókó sójú pátákó AKËKÕÖ a. Tëtí sí àlàyé olùkö lórí oríśiríśi ìsõrí gbólóhùn àti ìyàtõ wôn. b. Da àwôn àpççrç ìsõrí gbólóhùn tí olùkö kô sójú pátákó kô sínú ìwé d. Béèrè ìbéèrè löwö olùkö e. Dáhùn ìbéèrè olùkö ç. Śe àkôsílê sínú ìwé rç OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI Pátákó ìkõwé |
2. | ÀŚÀ: Àtúnyêwò àwôn õnà ìbánisõrõ Àrokò: oríśiríśi Oríśiríśi õnà tí a lè gbà pàrokòÌyàtõ láàrin ìpàrokò láyé àtijö àti òde òníÌwúlò àrokò ÀKÓÓNÚ IŚË Ohun tí ìbánisõrõ jë Oríśiríśi õnà ìbánisõrõ láyé àtijö d. Oríśiríśi õnà ìbánisõrõ láyé òde òní. e. Pàtàkì sísô èdè abínibí | OLÙKÖ a. Śàlàyé ohun tí ìbánisõrõ jë b. Śàlàyé oríśiríśi õnà ìbánisõrõ tí ó wà láyé àtijö àti òde òní d. Śàlàyé ìdí tí sísô èdè abínibí fi pôn dandan. AKËKÕÖ a. Sô ohun tí ìbánisõrõ jë b. Sô oríśiríśi õnà ìbánisõrõ láyé àtijö àti òde òní d. Sô õrõ láwùjô e. Jíròrò lórí ìdí tí a fi gbödõ máa sô èdè Yorùbá. OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI Àwòrán àmì ìpàrokò bí i owó çyô, ìkarahun ìgbín, ìgbálê, ìyarun àti bëê bëê lô Àwòrán àwôn àmì àrokò tòde òní Fídíò çni tí ó ń sõrõ láwùjô. |
3. | LÍTÍRÈŚÕ: Àśàyàn àwôn ìwé ewì alohùn (ìwé méjì) ÀKÓÓNÚ IŚË Kókó õrõ inú àwôn ewì alohùn náà Ìlò èdè inú àwôn ewì alohùn náà d. Àśà àti ìśe Yorùbá tó súyô nínú àwôn ewì alohùn náà e. õgangan ìró ewì alohùn tí a kà. Àwôn akéwì (êsìn/ iśë wôn) Ìlù, ijó ti wön ń lù sí i. Àkókò tí wön máa ń lo ewì náà Kíké àwôn ewì alohùn náà | OLÙKÖ a. Śe àlàyé kókó õrõ àwôn ewì alohùn náà fún akëkõö b. Śe àlàyé ìlò èdè inú àwôn ewì náà d. Tç êrô fídíò fún wôn tàbí darí akéwì alohùn láti ké àwôn ewì náà e. Tö akëkõö sönà láti ké ewì bí i méjì tàbí mëta láti inú àwôn ewì alohùn ìwé wôn ç. Fa àśà Yorùbá tó jçyô nínú ewì náà OHUN-ÈLÒ ÌKÖNI Ìwé ewì alohùn tí a yàn Fídíò àti fönrán tí a gba ewì alohùn sí Akéwì alohùn |
4. | Ìdánwò |
Senior Secondary School Humanities Syllabus for Yoruba. SS 3 Yoruba Language Scheme of Work Federal – Schemeofwork.com